Home Lyrics ojo nla lojo ti moyan

ojo nla lojo ti moyan

0
ojo nla lojo na mp3 download
ojo nla lojo na mp3 download

1. Ojo nla l’ ojo ti mo yan
Olugbala l’ Olorun mi;
Oye ki okan mi ma yo,
K’o si ro ihin na ka ‘le.

Ojo nla l’ ojo na!
Ti Jesu we ese mi nu
O ko mi ki nma gbadura
Ki nma sora ki nsi ma yo
Ojo nla l’ ojo na!
Ti Jesu we ese mi nu.

2. Ide mimo t’o s’ edidi
Eje mi f’ Eni ye ki nfe?
Jek’ orin didun kun ‘le Re
Nigba mo ban lo sin nibe.

3. Mo ti b’ Oluwa sadehun!
Mo di Tire, On di temi,
On l’o pe mi, ti mo si je,
Mo f’ ayo jipe mimo na.

4. Simi, okan aiduro mi,
Simi le Jesu Oluwa;
Ma f’ Oluwa re sile lai,
Lodo Re n’ ire re gbe wa.

5. ‘Wo orun t’o gbo eje mi
Y’o ma tun gbo lojojumo,
Tit’ ojo t’ emi mi y’o pin,

Ti ngo mu majemu na se.