Mo n tesiwaju lona na lyrics

Ojo Nla L'ojo Na In English
Ojo Nla L'ojo Na In English

Mo n tesiwaju lona na lyrics

Mo n te siwaju lona na
Mo n goke si lojojumo
Mo n gbadura bi mo ti n lo
Oluwa jo gbe mi soke

Refrain:
Oluwa jo gbe mi soke
Fami lo si ibi giga
Apata to ga jumi lo
Oluwa jo gbe mi soke

Ife okan mi ko duro
Larin ‘yemeji at’eru
Awon miran le ma gbe’be
Ibi giga lokan mi fe

Mo fe ki nga ju aye lo
Ninu ogo didan julo
Mo ngbadura ki nle de ‘be
Oluwa mumi de ‘le na.

Fa mi lo si ibi giga
L’aisi Re nko ni le de ‘be
Fa mi titi d’oke orun
Ki nkorin lat’ibi giga.